42. nítorí tí àwọn ènìyàn yóò gbọ́ orúkọ ńlá rẹ, àti ọwọ́ agbára rẹ, àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá sì wá, tí ó sì gbàdúrà sí ìhà ilé yìí,
43. nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí àlejò náà yóò bèèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo ènìyàn ní ayé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọn kí ó sì máa bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì le mọ̀ pé orúkọ rẹ ni a fi pe ilé yìí tí mo kọ́.
44. “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá jáde lọ sí ogun sí àwọn ọ̀ta wọn, níbikíbi tí ìwọ bá rán wọn, nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí Olúwa sí ìhà ìlú tí ìwọ ti yàn àti síhà ilé tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ,
45. nígbà náà ni kí o gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró.
46. “Nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ sí ọ, nítorí kò sí ẹnìkan tí kì í ṣẹ̀, tí ìwọ sì bínú sí wọn, tí ìwọ sì fi wọ́n lé ọ̀tá lọ́wọ́, tí ó kó wọn ní ìgbékùn lọ sí ilẹ̀ wọn, jínjìnnà tàbí nítòòsí;
47. bí wọ́n bá ní ìyípadà ọkàn ní ilẹ̀ níbi tí a kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n bá sì ronúpìwàdà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ sí ọ ní ilẹ̀ àwọn tí ó kó wọn ní ìgbékùn lọ, wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀, àwa ti ṣe ohun tí kò tọ́, àwa ti ṣe búburú’;