13. Nítòótọ́ èmi ti kọ́ ilé kan fún ọ, ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láéláé.”
14. Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì dúró síbẹ̀, ọba sì yí ojú rẹ̀, ó sì bùkún fún wọn.
15. Nígbà náà ni ó wí pé:“Ìbùkún ni fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ìlérí tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dáfídì bàbá mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé,
16. ‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Éjíbítì, èmi kò tí ì yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi láti wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n èmi ti yan Dáfídì láti ṣàkóso àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi.’
17. “Dáfídì baba mi sì ní i lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
18. Ṣùgbọ́n Olúwa sì wí fún Dáfídì bàbá mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi, ó dára láti ní èyí ní ọkàn rẹ.
19. Ṣùgbọ́n, ìwọ kọ ni yóò kọ́ ilé náà, ṣùgbọ́n ọmọ rẹ, tí ó tinú ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ jáde; òun ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’
20. “Olúwa sì ti pa ìlérí rẹ̀ tí ó ṣe mọ́: Èmi sì ti rọ́pò Dáfídì bàbá mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì báyìí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí, èmi sì kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
21. Èmi sì ti pèsè ibìkan níbẹ̀ fún àpótí-ẹ̀rí, èyí tí í ṣe májẹ̀mú Olúwa tí ó ti bá àwọn baba wa dá nígbà tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá.”
22. Sólómónì sì dúró níwájú pẹpẹ Olúwa, níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè ọ̀run.
23. Ó sì wí pé:“Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ lókè ọ̀run tàbí ní ìṣàlẹ̀ ilẹ̀ ìwọ tí ó pa májẹ̀mú àti àánú mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ.
24. O sì ti pa ìlérí rẹ mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì baba mi; pẹ̀lú ẹnu rẹ ni ìwọ ṣe ìlérí, o sì mú u ṣẹ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, bí ó ti rí lónìí.
25. “Ǹjẹ́ báyìí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, bá ìránṣẹ́ rẹ̀ Dáfídì bàbá mi pa ohun tí ìwọ ti ṣe ìlérí fún un mọ́ wí pé, Iwọ kì yóò kùnà láti ní ènìyàn kan láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ bá lè kíyèsí ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa rìn níwájú mi bí ìwọ ti rìn.
26. Ǹjẹ́ báyìí, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣe ìlérí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Dáfídì baba mi wá sí ìmúṣẹ.
27. “Ṣùgbọ́n nítòótọ́ Ọlọ́run yóò máa gbé ayé bí? Ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò le gbà ọ́. Kí a má sọ pé ilé yìí tí mo kọ́ fún ọ!
28. Síbẹ̀ ṣe ìfetísílẹ̀ àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ fún àánú, Olúwa Ọlọ́run mi. Gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ lónìí.