8. Ààfin rẹ̀ níbi tí yóò sì gbé wà ní àgbàlá lẹ́yìn ààfin, irú kan náà ni wọ́n. Sólómónì sì kọ́ ààfin tí ó rí bí gbàngàn yìí fún ọmọbìnrin Fáráò tí ó ní ní aya.
9. Gbogbo wọ̀nyí láti òde dé apá àgbàlá ńlá, àti láti ìpìlẹ̀ dé ìbòrí òkè ilé, wọ́n sì jẹ́ òkúta iyebíye gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n òkúta gbígbẹ, tí a fi ayùn rẹ́ nínú àti lóde.
10. Ìpìlẹ̀ náà jẹ́ òkúta iyebíye, àní òkúta ńlá ńlá, àwọn mìíràn wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ̀wàá, àwọn mìíràn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ.
11. Lókè ni òkúta iyebíye wà nípa ìwọ̀n òkúta tí a gbé àti igi kédárì.
12. Àgbàlá ńlá náà yíkákiri ògiri pẹ̀lú ọ̀wọ́ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ọ̀wọ́n kan igi ìdábùú ti kédárì, bí ti inú lọ́hùn ún àgbàlá ilé Olúwa pẹ̀lú ìloro rẹ̀.
13. Sólómónì ọba ránṣẹ́ sí Tírè, ó sì mú Hírámù wá,