1 Ọba 7:48-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

48. Sólómónì sì tún ṣe gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ tí ń ṣe ti ilé Olúwa pẹ̀lú:pẹpẹ wúrà;tabílì wúrà lórí èyí tí àkàrà ìfihàn gbé wà;

49. Ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà, márùn-ún ní apá ọ̀tún àti márùn ún ní apá òsì, níwájú ibi mímọ́ jùlọ; ìtànná ewéko;fìtílà àti ẹ̀mú wúrà;

50. Ọpọ́n kìkì wúrà, àlùmágàjí fìtílà, àti àwo kòtò, àti ṣíbí àti àwo tùràrí ti wúrà dáradára;àti àgbékọ́ wúrà fún ilẹ̀kùn inú ilé ibi mímọ́ jùlọ àti fún ilẹ̀kùn ilé náà, àní ti tẹ́ḿpìlì.

1 Ọba 7