1 Ọba 5:8-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Hírámù sì ránṣẹ́ sí Sólómónì pé:“Èmi ti gbọ́ iṣẹ́ tí ìwọ rán sí mi, èmi yóò sì ṣe gbogbo èyí tí o fẹ́ ní pípèsè igi Kédárì àti ní ti igi fírì.

9. Àwọn ènìyàn mi yóò mú igi náà sọ̀kalẹ̀ láti Lébánónì wá sí òkun, èmi ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọ ní fífò lójú omi òkun títí dé ibi tí ìwọ ó na ìka sí fún mi. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ìwọ yóò sì kó wọn lọ. Ìwọ yóò sì gba ìfẹ́ mi nípa pípèsè oúnjẹ fún ilé mi.”

10. Báyìí ni Hírámù sì pèsè igi Kédárì àti igi fírì tí Sólómónì ń fẹ́ fún un,

11. Sólómónì sì fún Hírámù ní ẹgbàawá (20,000) òṣùwọ̀n ọkà oúnjẹ fún ilé rẹ̀, àti ogún (20) òṣùwọ̀n òróró dáradára. Sólómónì sì ń tẹ̀ṣíwájú láti ṣe èyí fún Hírámù lọ́dọọdún.

12. Olúwa sì fún Sólómónì ní ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un. Ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà sì wà láàrin Hírámù àti Sólómónì, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn.

13. Sólómónì ọba sì sa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Ísírẹ́lì; àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún ènìyàn (30,000).

14. Ó sì rán wọn lọ sí Lébánónì, ẹgbàárún (10,000) lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lébánónì, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì. Ádónírámù ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà.

15. Sólómónì sì ní ẹgbàá márùndínlógójì (70,000) ènìyàn tí ń ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) gbẹ́nàgbẹ́nà lórí òkè,

16. àti àwọn ìjòyè nínú àwọn tí a fi ṣe olórí iṣẹ́ Sólómónì jẹ́ ẹgbẹ̀rindínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún (3,300) ènìyàn, tí ó ń ṣe aláṣẹ àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ náà.

17. Ọba sì pàṣẹ, wọ́n sì mú òkúta wá, òkúta iyebíye, àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ìpìlẹ̀ ilé náà lé ilẹ̀.

18. Àwọn oníṣọ̀nà Sólómónì àti Hírámù àti àwọn ènìyàn Gébálì sì gbẹ́ wọn, wọ́n sì pèsè igi àti òkúta láti fi kọ́ ilé náà.

1 Ọba 5