1. Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Nábótì ará Jésérẹ́lì sì ní ọgbà àjàrà kan ní Jésérẹ́lì, ní ẹ̀gbẹ́ ààfin Áhábù ọba Samáríà.
2. Áhábù sì wí fún Nábótì pé, “Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ, kí èmi kí ó fi ṣe ọgbà-ewébẹ̀, nítorí tí ó súnmọ́ tòsí ilé mi; Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó sàn jù ú lọ dípò rẹ̀; tàbí bí ó bá sì dára ní ojú rẹ, èmi yóò fi iye owó rẹ̀ fún ọ.”
3. Ṣùgbọ́n Nábótì wí fún Áhábù pé, “Olúwa má jẹ́ kí èmi fi ogún àwọn bàbá mi fún ọ.”
4. Áhábù sì wá sí ilé rẹ̀, ó wugbọ́, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí Nábótì ará Jésérẹ́lì sọ fún un; nítorí tí ó wí pé, “Èmi kì yóò fún ọ ní ogún àwọn bàbá mi.” Ó sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó sì yí ojú rẹ̀ padà, kò sì fẹ́ jẹun.