5. Àwọn ońṣẹ́ náà sì tún padà wá, wọ́n sì wí pé, “Báyìí ni Bẹni-Hádádì sọ wí pé: ‘Mo ránṣẹ́ láti béèrè fún fàdákà rẹ àti wúrà rẹ, àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ.
6. Ṣùgbọ́n ní ìwòyí ọ̀la Èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ láti wá ilé rẹ wò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Wọn yóò gba gbogbo ohun tí ó bá dára lójú rẹ, wọn yóò sì kó o lọ.’ ”
7. Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì pe gbogbo àwọn àgbà ìlú, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wo bí ọkùnrin yìí ti ń fẹ́ ìyọnu! Nígbà tí ó ránṣẹ́ fún àwọn aya mi, àti fún àwọn ọmọ mi, àti fún fàdákà mi, àti fún wúrà mi, èmi kò sì fi dù ú.”
8. Àwọn àgbà àti gbogbo ènìyàn dá a lóhùn pé, “Má se fi etí sí tirẹ̀ tàbí kí o gbà fún un.”
9. Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Bẹni-Hádádì pé, “Sọ fún Olúwa mi ọba pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe ohun gbogbo tí ó ránṣẹ́ fún látètèkọ́ṣe, ṣùgbọ́n nǹkan yìí ni èmi kò le ṣe.’ ” Wọ́n padà lọ, wọ́n sì mú èsì padà wá fún Bẹni-hádádì.