11. Ọba Ísírẹ́lì sì dáhùn wí pé, “Sọ fún un pé: ‘Má jẹ́ kí ẹni tí ń hámọ́rà halẹ̀ bí ẹni tí ń bọ́ ọ sílẹ̀.’ ”
12. Bẹni-Hádádì sì gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí nigbà tí òun àti àwọn ọba ń mu ọtí nínú àgọ́ wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Ẹ tẹgun sí ìlú náà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe tan láti kọlu ìlú náà.
13. Sì kíyèsí i, wòlíì kan tọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì wá, ó sì wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ rí gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun yìí? Èmi yóò fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ lónìí, nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”
14. Áhábù sì béèrè pé, “Ṣùgbọ́n ta ni yóò ṣe èyí?”Wòlíì náà sì dáhùn wí pé, “Ìwọ ni yóò ṣe é.”
15. Nígbà náà ni Áhábù ka àwọn ìjòyè kéékèèkéé ìgbéríko, wọ́n sì jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n. (232) Nígbà náà ni ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù jọ, gbogbo wọn sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin. (700)