5. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un. Ó sì lọ sí ẹ̀bá odò Kérítì, tí ń bẹ níwájú Jọ́dánì, ó sì dúró síbẹ̀.
6. Àwọn ẹyẹ ìwò sì mú àkàrà àti ẹran wá fún un ní òwúrọ̀, àti àkàrà àti ẹran ní alẹ́, ó sì ń mu nínú odò náà.
7. Ó sì ṣe lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, odò náà sì gbẹ nítorí kò sí òjò ní ilẹ̀ náà.
8. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá wí pé:
9. “Lọ nísinsìn yìí sí Ṣáréfátì ti Ṣídónì, kí o sì dúró síbẹ̀. Èmi ti pàṣẹ fún obìnrin opó kan níbẹ̀ láti máa bọ́ ọ.”
10. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sí Ṣáréfátì. Nígbà tí ó sì dé ibodè ìlú náà, obìnrin opó kan ń ṣa igi jọ níbẹ̀. Ó sì ké sí i, ó sì béèrè pé, “Ǹjẹ́ o lè bu omi díẹ̀ fún mi wá nínú ohun èlò kí èmi kí ó lè mu?”
11. Bí ó sì ti ń lọ bù ú wá, ó ké sí i pé, “Jọ̀ ọ́, mú òkèlè oúnjẹ díẹ̀ fún mi wá lọ́wọ́ rẹ.”