34. “ ‘Ṣùgbọ́n èmi kì yóò gba gbogbo ìjọba náà lọ́wọ́ Sólómónì; èmi ti mú un jẹ́ olórí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi, ẹni tí mo yàn, tí ó sì ti pa òfin mi àti àṣẹ mi mọ́.
35. Èmi yóò gba ìjọba náà ní ọwọ́ ọmọ rẹ̀, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ̀wàá fún ọ.
36. Èmi yóò fi ẹ̀yà kan fún ọmọ rẹ kí Dáfídì ìránṣẹ́ mi lè máa ní ìmọ́lẹ̀ níwájú mi nígbà gbogbo ní Jérúsálẹ́mù, ìlú tí mo ti yàn láti fi orúkọ mi síbẹ̀.
37. Ṣùgbọ́n ní ti ìwọ, Èmi yóò mú ọ, ìwọ yóò sì jọba lórí ohun gbogbo tí ọkàn rẹ ń fẹ́; ìwọ yóò jọba lórí Ísírẹ́lì.
38. Bí ìwọ bá ṣe gbogbo èyí tí mo pàṣẹ fún ọ, tí o sì rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú mi nípa pípa òfin àti àṣẹ mi mọ́, bí i Dáfídì ìránṣẹ́ mi ti ṣe, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò kọ́ ilé òtítọ́ fún ọ bí èyí tí mo kọ́ fún Dáfídì, èmi yóò sì fi Ísírẹ́lì fún ọ.
39. Èmi yóò sì rẹ irú ọmọ Dáfídì sílẹ̀ nítorí èyí, ṣùgbọ́n kì í ṣe títí láé.’ ”
40. Sólómónì wá ọ̀nà láti pa Jéróbóámù, ṣùgbọ́n Jéróbóámù sá lọ sí Éjíbítì, sọ́dọ̀ Ṣísákì ọba Éjíbítì, ó sì wà níbẹ̀ títí Sólómónì fi kú.
41. Ìyòókù iṣẹ́ Sólómónì àti gbogbo èyí tí ó ṣe, àti ọgbọ́n rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìṣe Sólómónì bí?
42. Sólómónì sì jọba ní Jérúsálẹ́mù lórí gbogbo Ísírẹ́lì ní ogójì ọdún.
43. Nígbà náà ni ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì baba rẹ̀. Réhóbóámù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.