14. Èmi kò kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí láti fi dójútì yín, ṣùgbọ́n láti kìlọ̀ fún un yín bí àwọn ọmọ mi tí mo yàn fẹ́.
15. Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbààrún olùkọ́ni nínú Kírísítì, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀; nítorí nínú Kírísítì Jésù ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìyìn rere.
16. Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi.
17. Nítorí náà ni mo ṣe rán Tìmótíù sí i yín, ẹni tí í ṣe ọmọ mi olùfẹ́ àti olódodo nínú Olúwa, ẹni tí yóò máa mú yín rántí ọ̀nà mi tí ó wà nínú Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ni nínú gbogbo ìjọ níbi gbogbo.
18. Mo mọ̀ pé àwọn mìíràn nínú yín tó ya onígbéraga ènìyàn, tí wọn ń rò pé ẹ̀rù ń bà ni láti wá sọ́dọ̀ yín láti ṣe ẹ̀tọ́ fún un yín.
19. Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yín wá ní àìpẹ́ yìí, bí Olúwa bá fẹ́; èmi yóò ṣe ìwádìí bí àwọn agbéraga yìí se ń sọ̀rọ̀ àti agbára tí wọ́n ní.
20. Nítorí ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe nínú ọ̀rọ̀, bí kò ṣe nínú agbára.
21. Èwo ni ẹ yàn? Kí ń wá sọ́dọ̀ yín pẹ̀lú pàsán, tàbí ni ìfẹ̀, àti ẹ̀mí tútù?