1 Kọ́ríńtì 2:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Kí ìgbàgbọ́ yín kí ó má ṣe dúró lórí ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ó dúró lórí agbára Ọlọ́run.

6. Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrin àwọn tí a pè; ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán

7. Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó farasin, ọgbọ́n tí ó ti farapamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa.

8. Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀: ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀, wọn kì bá tún kan ọba ògo mọ́ àgbélébùú.

9. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Ojú kò tíì rí,etí kò tí í gbọ́,kò sì ọkàn tí ó tí í mọ̀ènìyànohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ Ẹ.”

1 Kọ́ríńtì 2