1 Kọ́ríńtì 16:11-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin.

12. Ṣùgbọ́n ní ti Àpólò arákùnrin wa, mo bẹ́ẹ̀ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin: Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsìnyìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbá tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.

13. Ẹ máa ṣọra, ẹ dúró gbọingbọin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára.

14. Ẹ máa ṣe gbogbo nínú ìfẹ́.

15. Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ sá mọ ilé Sítéfánà, pé àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jésù ní Ákáyà, àti pé, wọn sì tí fí ará wọn fún iṣẹ́-iránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́.

16. Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbásiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá.

17. Mo láyọ̀ fún wíwá Sítéfánà àti Fórítúnátù àti Ákáyákù: nítorí èyí tí ó kù nípá tí yín wọ́n ti fí kún un.

18. Nítorí tí wọ́n tu ẹ̀mí mí lára àti tiyín: nítorí náà, ẹ máa gba ìru àwọn ti ó rí bẹ́ẹ̀.

19. Àwọn ìjọ ni Ásíà kí í yín, Àkúílà àti Pìrìsílà kí í yín púpọ̀ nínú Olúwa, pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ni ilé wọn.

20. Gbogbo àwọn arákùnrin kí í yín, ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.

21. Ìkíni ti èmi Pọ́ọ̀lù, láti ọwọ́ èmi tìkáraàmi wá.

22. Bí ẹníkẹ́ní kò bá ní ìfẹ́ Jesu Kírísítì Olúwa, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú. Máa bọ Olúwa wa!

23. Oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa kí ó wà pẹ̀lú yín!

1 Kọ́ríńtì 16