34. Ẹ ji ìjí òdodo, kí ẹ má sì dẹ́ṣẹ̀; nítorí àwọn ẹlómírán kò ni imọ̀ Ọlọ́run: mo sọ èyí kí ojú baà lè ti yín.
35. Ṣùgbọ́n ẹnìkan yóò wí pé, “Báwo ni àwọn òkú yóò ṣe jíǹde? Irú ara wó ni wọn ó padà sí?”
36. Iwọ aláìmòye, ohun tí ìwọ fúnrúgbìn kì í yè bí kò ṣe pé ó kú:
37. Àti èyí tí ìwọ fúnrúgbìn, kì í ṣe ara tí ń bọ̀ ni ìwọ fúnrúgbìn, ṣùgbọ́n irúgbín lásán ni, ìbáàṣe àlìkámà, tabi irú mìíràn.
38. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún ún ni ara bí o tí wù ú, àti fún olúkúlùkù irú ara tirẹ̀.
39. Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe ẹran-ara kan náà: ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ènìyàn, ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ní ti ẹja, ọ̀tọ̀ sì ní tí ẹyẹ.