30. Nítorí kínní àwa sì ṣe ń bẹ nínú ewu ni wákàtí gbogbo?
31. Mo sọ nípa ayọ̀ tí mo ní lórí yín nínú Kírísítì Jésù Olúwa wá pé, èmi ń kú lojoojúmọ.
32. Kí a wí bí ènìyàn, bí mo bá ẹranko jà ní Éfésù, àǹfàání kín ni ó jẹ́ fún mi? Bí àwọn òkú kò bá jínde,“Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ kí á máa mú;nítorí ní ọlá ni àwa ó kú.”
33. Kí a má tàn yín jẹ́: “Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́!?”
34. Ẹ ji ìjí òdodo, kí ẹ má sì dẹ́ṣẹ̀; nítorí àwọn ẹlómírán kò ni imọ̀ Ọlọ́run: mo sọ èyí kí ojú baà lè ti yín.
35. Ṣùgbọ́n ẹnìkan yóò wí pé, “Báwo ni àwọn òkú yóò ṣe jíǹde? Irú ara wó ni wọn ó padà sí?”
36. Iwọ aláìmòye, ohun tí ìwọ fúnrúgbìn kì í yè bí kò ṣe pé ó kú:
37. Àti èyí tí ìwọ fúnrúgbìn, kì í ṣe ara tí ń bọ̀ ni ìwọ fúnrúgbìn, ṣùgbọ́n irúgbín lásán ni, ìbáàṣe àlìkámà, tabi irú mìíràn.
38. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún ún ni ara bí o tí wù ú, àti fún olúkúlùkù irú ara tirẹ̀.