1 Kọ́ríńtì 14:26-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ǹjẹ́ è é ha ti ṣe, ki ni ki àwa yóò sọ ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ̀yin pé jọ pọ̀, tí olúkúlùkù yín ni Sáàmù kan tàbí ẹ̀kọ́ kan, èdè kan, ìfihàn kan, ìtumọ̀ kan. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láti gbé ìjọ ró.

27. Bí ẹnìkan bá fi èdè fọ̀, kí ó jẹ ènìyàn méjì, tàbi bí ó pọ̀ tán, kí ó jẹ́ mẹ́ta, kí ó sọ̀rọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí ẹnìkan sì túmọ̀ rẹ̀,

28. Ṣùgbọ́n bí kò bá sí ògbufọ̀, kí ó pá ẹnu rẹ̀ mọ́ nínú ìjọ; sì jẹ́ kí ó máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀.

1 Kọ́ríńtì 14