1 Kọ́ríńtì 1:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nítorí Kírísítì kò rán mi láti máa ṣe ìtẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n Ó rán mi láti máa wàásù ìyìn rere: kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn, kí a máa ṣe sọ àgbélébú Kírísítì dí aláìlágbára.

18. Nítorí pé òmùgọ̀ ni ọ̀rọ̀ àgbélébùú jẹ́ sí àwọn tí ń sègbé, ṣùgbọ́n fún àwa tí a ń gbàlà ó jẹ́ agbára Ọlọ́run

19. Nítorí tí kọ ọ́ pé:“Èmi yóò pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run,òye àwọn olóye ni Èmi yóò sọ di asán.”

20. Àwọn ọlọ́gbọ́n ha dá? Àwọn ọ̀mọ̀wé ha dà? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ayé yìí ha dà? Ọlọ́run kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di òmùgọ̀?

1 Kọ́ríńtì 1