6. Níti ará Ṣérà:JégúélìÀwọn ènìyàn láti júdà sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690).
7. Níti ará:Ṣálù ọmọ Mésúlámì, ọmọ Hódáfíà; ọmọ Hásénúà;
8. Íbínéíà ọmọ Jéróhámù; Élà ọmọ Húṣì, ọmọ Míkírì àti Mésúlámù ọmọ Ṣéfátíyà; ọmọ Régúélì, ọmọ Íbíníjà.
9. Àwọn ènìyàn láti Bẹ́ńjámínì gẹ́gẹ́ bí a ti se kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rùn ún ó dín mẹ́rìnlélógójì, (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé.
10. Ní ti àwọn àlùfáà:Jédáíà; Jéhóíáríbì; Jákínì;
11. Áṣáríyà ọmọ Hílíkíyà, ọmọ Mésúlámù, ọmọ Ṣádókù, ọmọ Méráíótù, ọmọ Áhítúbì, onísẹ́ tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run;
12. Ádáyà ọmọ Jéróhámù, ọmọ Páṣúrì, ọmọ Málíkíjà; àti Másáì ọmọ Ádíélì, ọmọ Jáhíṣérà, ọmọ Mésúlámù ọmọ Méṣílémítì, ọmọ Ímérì
13. Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì (1,760). Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run.