1 Kíróníkà 8:37-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

37. Móṣà jẹ́ baba a Bínéà; Ráfà sì jẹ́ ọmọ Rẹ̀, Éléásà ọmọ Rẹ̀ àti Áṣélì ọmọ Rẹ̀.

38. Áṣélì ní ọmọ mẹ́fà pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn:Áṣíríkámù, Bókérù, Íṣímáélì, Ṣéáríà, Ọbádáyà àti Hánánì. Gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Áṣélì.

39. Àwọn ọmọ arákùnrin Rẹ̀ Éṣékì:Úlámù àkọ́bí Rẹ̀, Jéúṣì ọmọkùnrin ẹ̀ẹ̀kejì àti Élífélétì ẹ̀ẹ̀kẹ́ta.

40. Àwọn ọmọ Úlámù jẹ́ ògboyà jagunjagun tí ó lè gbá orin mú. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọ ọmọkùnrin márùndínlọ́gọ́jọ ní gbogbo Rẹ̀.Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ìran ọmọ Bẹ́ńjámínì.

1 Kíróníkà 8