1 Kíróníkà 8:25-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ífédíà Pénúélì jẹ́ àwọn ọmọ Ṣásákì.

26. Ṣámíséráì, Ṣéháríà, Átalíà

27. Járéṣíà Élíjà àti Ṣíkírì jẹ́ àwọn ọmọ Jéróhámù.

28. Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn ìdílé, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ó lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.

29. Jélíélì, baba a Gíbíónì ń gbé ní Gíbíónì.Ìyáwó o Rẹ̀ a má jẹ́ Mákà,

30. Àkọ́bí Rẹ̀ a sì má a jẹ́ Ábídónì wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Ṣúrì, Kíṣì, Báláhì, Nérì, Nádábù,

31. Gédórì Áhíò, Ṣékérì

32. Pẹ̀lú Míkílótì, tí ó jẹ́ bàbá Ṣíméà. Wọ́n ń gbé lébá ìbátan wọn ní Jérúsálẹ́mù.

1 Kíróníkà 8