1 Kíróníkà 6:32-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin ńiwájú Àgọ́ ìpàdé títí tí Ṣólómónì fi kọ́ ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù. Wọ́n se iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.

33. Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn:Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kóhátítè:Hémánì olùkọrin,ọmọ Jóẹ́lì, ọmọ Ṣámúẹ́lì,

34. Ọmọ Élíkánáhì ọmọ Jéróhámù,ọmọ Élíéli, ọmọ Tóhà

35. Ọmọ Ṣúfì, ọmọ Élíkáná,ọmọ Máhátì, ọmọ Ámásáyì,

36. Ọmọ Élíkánà, ọmọ Jóẹ́lì,ọmọ Ásárááhì, ọmọ Ṣéfáníáhì

37. Ọmọ Táhátì, ọmọ Áṣírì,ọmọ Ébíásáfì ọmọ Kóráhì,

38. ọmọ Íṣíhárì, ọmọ Kóhátìọmọ Léfì, ọmọ Ísírẹ́lì;

39. Hémánì sì darapọ̀ mọ́ Ásátì, ẹni tí Ó sìn ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀:Ásátì ọmọ bérékíáhì, ọmọ Ṣíméà,

40. Ọmọ Míkáélì, ọmọ Bááséíáhì,ọmọ Málíkíjáhì

41. Ọmọ Étínì,ọmọ Ṣéráhì, ọmọ Ádáyà,

42. Ọmọ Étanì, ọmọ Ṣímáhì,ọmọ Ṣíméhì,

43. Ọmọ Jáhátì,ọmọ Gérísíónì, ọmọ Léfì;

1 Kíróníkà 6