20. Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hágárì lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí ti wọn képe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.
21. Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ; ràkunmí ẹgbàámẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùnún, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbàá, àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn ún.
22. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ṣubú tí a pa, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ogun náà, wọ́n sì jókòó ní ipò wọn títí di ìgbà ìkólọ sí ìgbékùn.
23. Àwọn ọmọkùnrin ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ń gbé ní ilẹ̀ náà: wọ́n bí sí i láti Básánì títí dé Báálì-hérímónì, àti Ṣénírì àti títí dé òkè Hérímónì.