2. Ó sì kó gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì.
3. Àwọn ọmọ Lefì lati ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún (38,000)
4. Dáfídì sì wí pe, Níti èyí, ẹgbàáméjìlá (24,000) ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbàáta (6,000) ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́.
5. Ẹgbàájì (4,000) ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà àti ẹgbàajì (4,000) ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti se èyí fún ìdí pàtàkì yìí.