1 Kíróníkà 22:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà Dáfídì wí pé, “Ilé Olúwa Ọlọ́run ni ó gbọdọ̀ wà níbí, àti pẹ̀lú pẹpẹ ọrẹ síṣun fún Ísírẹ́lì.”

2. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì paláṣẹ láti kó àwọn àlejò tí ń gbé ní Ísírẹ́lì jọ, àti wí pé lára wọn ni ó ti yan àwọn agbé-òkúta láti gbé òkúta dáradára láti fi kọ́lé Ọlọ́run.

3. Ó sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye irin láti fi ṣe ìṣọ́ fún àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà àti fún idẹ; àti fún òpó idẹ ni àìní ìwọ̀n.

1 Kíróníkà 22