1 Kíróníkà 2:42-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Àwọn ọmọ Kálébù arákùnrin Jérámélì:Méṣà àkọ́bí Rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Ṣífì àti àwọn ọmọ Rẹ̀ Méréṣà, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hébúrónì.

43. Àwọn ọmọ Hébúrónì:Kórà, Tápúà, Rékémù, àti Ṣémà.

44. Ṣémà ni baba Ráhámú Ráhámù sì jẹ́ baba fún Jóríkéámù. Rékémù sì ni baba Ṣémáì.

45. Àwọn ọmọ Ṣémáì ni Máónì, Máónì sì ni baba Bétí-Ṣúri.

46. Éfà Obìnrin Kélẹ́bù sì ni ìyá Hárà nì, Mósà àti Gásésì, Háránì sì ni baba Gásésì.

1 Kíróníkà 2