1 Kíróníkà 19:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nígbà náà Jóábù àti àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú Rẹ̀ lọṣíwájú láti lọ jà pẹ̀lú àwọn ará Ṣíríà. Wọ́n sì sálọ kúrò níwájú Rẹ̀.

15. Nígbà ti àwọn ará Ámónì ri pé àwọn ará Ṣíríà ń sálọ, àwọn náà sálọ kúrò níwájú arákùnrin Rẹ̀ Ábíṣáì. Wọ́n sì wọ inú ìlú ńlá lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Jóábù padà lọ sí Jérúsálẹ́mù.

16. Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ará Ṣíríà rí wí pé àwọn Ísírẹ́lì ti lé wọn, wọ́n rán ìránṣẹ́. A sì mú àwọn ará Ṣíríà rékọjá odò wá, pẹ̀lú Ṣófákì alákóso ọmọ ogun Hádádésérì, tí ó ń darí wọn.

1 Kíróníkà 19