30. àwọn arákùnrin Éfúráímù, ògbójú akọni, ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n nílé baba wọn ẹgbàwá ó le ẹgbẹ̀rin (20,800)
31. Àwọn ọkùnrin nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, tí a yàn nípa orúkọ láti wá àti láti yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba-ẹgbàásàn (18,000).
32. Àwọn ọkùnrin Ísákárì, àwọn ẹni tí ó mọ ìgbà yẹn ó sì mọ ohun tí Ísírẹ́lì yóò se ìgbà (200) àwọn ìjòyè, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìbátan wọn lábẹ́ òfin wọn.
33. Àwọn ọkùnrin Ṣébúlúnì, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú orísirísi ohun èlò ìjà, láti ran Dáfídì lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàámẹ́dọ́gbọ̀n (50,000);