1 Kíróníkà 12:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Jóhánánì ẹlẹ́kẹ́jọ Élísábádì ẹlẹ́ẹ̀kẹ́sàn-án

13. Jeremíàh ẹlẹ́kẹ́wàá àti Mákíbánáì ẹlẹ́kọ́kànlá.

14. Àwọn ará Gádì wọ́n sì jẹ́ olórí ogun; ẹni tí ó kéré jù sì jẹ́ àpapọ̀ ọgọ́rùn-ún, àti fún ẹni tí ó pọ̀jù fún ẹgbẹ̀rún.

15. Àwọn ni ẹni tí ó rékọjá Jọ́dánì ní oṣù àkọ́kọ́ nígbà tí ó kún bo gbogbo bèbè Rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tí ó ń gbé nínú àfonífojì, lọ sí ìlà oòrùn àti níhà ìwọ̀ oòrùn.

16. Ìyòókù ará Bẹ́ńjámínì àti àwọn díẹ̀ ọkùnrin láti Júdà lọ sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ní ibi gíga.

1 Kíróníkà 12