1 Kíróníkà 10:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísinsin yìí, àwọn ará Fílístínì dojú ìjà kọ Ísírẹ́lì, Àwọn ará ísírélì sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí ọri òkè Gílíbóà

2. Àwọn ará Fílístínì sí lépa Sáúlù gidigidi àti àwọn ọmọ Rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ Rẹ̀. Jónátanì, Ábínádábù àti Málíkíṣúà.

3. Ìjà náà sì ń gbóná síi yí Sáúlù ká. Nígbà tí àwọn tafàtafà sì lé e bá, wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́.

4. Ṣọ́ọ̀lù sì sọ fún ẹni tí ó gbé ìhámọ́ra Rẹ̀ pé, Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má wá láti bú mi.Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń gbé ìhámọ́ra Rẹ̀ ń bẹ̀rù, kò sì le ṣe é; Bẹ́ẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù mú idà tirẹ̀ ó sì subú lé e.

5. Nígbà tí agbé-ìhámọ́ra rí pé Ṣọ́ọ̀lù ti kú, òhun pẹ̀lú subú lórí idà tirẹ̀, ó sì kú.

6. Bẹ́ẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ Rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú gbogbo ilé Rẹ̀ sì kú lápapọ̀.

1 Kíróníkà 10