1 Kíróníkà 10:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísinsin yìí, àwọn ará Fílístínì dojú ìjà kọ Ísírẹ́lì, Àwọn ará ísírélì sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí ọri òkè Gílíbóà

2. Àwọn ará Fílístínì sí lépa Sáúlù gidigidi àti àwọn ọmọ Rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ Rẹ̀. Jónátanì, Ábínádábù àti Málíkíṣúà.

3. Ìjà náà sì ń gbóná síi yí Sáúlù ká. Nígbà tí àwọn tafàtafà sì lé e bá, wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́.

1 Kíróníkà 10