7. Àwọn ọmọ Jáfánì:Èlíṣà, Tárísísì, Kítímù, àti Dódánímù.
8. Àwọn ọmọ Ámù:Kúṣì, Ṣébà, Mísíráímù, Pútì, àti Kénánì.
9. Àwọn ọmọ Kúṣì:Ṣébà Háfílà, Ṣébítà, Rámà, àti Ṣábítékà,Àwọn ọmọ Rámà:Ṣébà àti Dédánì.
10. Kúṣì ni baba Nímíródù:Ẹni tí ó dàgbà tí ó sì jẹ́ jagunjagun alágbára lórí ilẹ̀ ayé.
11. Mísíráímù ni babaLúdímù, Ánámímù, Léhábímù, Náfítúhímù,
12. Pátírísímù, Kásiliúhímù, (Láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Fílístínì ti wá) àti Káfitórímù.
13. Kénánì ni babaṢídónì àkọ́bí Rẹ̀, àti ti àwọn ará Hítì,
14. Àwọn ará Jébúsì, àwọn ará Ámórì, àwọn ará Gírígásì
15. Àwọn Hífì, àwọn ará Áríkì, àwọn ará Hamati-Ṣínì,
16. Àwọn ará Árífádù, àwọn ará, Ṣémárì, àwọn ará Hámátì.
17. Àwọn ọmọ Ṣémù:Élámù. Ásúrì, Árífákásádì, Lúdì àti Árámù.Àwọn ará Árámù:Usì Húlì, Gétérì, àti Méṣékì.
18. Árífákásádì sì jẹ́ Baba Ṣélà,àti Ṣélà sì jẹ́ Baba Ébérì.
19. A bí àwọn ọmọ méjì fún Ébérì:Orúkọ ọ̀kan ni Pélégì, nítorí ní àkókò tirẹ̀ a pín ayé; orúkọ ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ ọkùnrin a sì máa jẹ́ Jókítanì.
20. Jókítanì sì jẹ́ Baba fúnHímódádì, Ṣéléfì, Hásárímáfétì, Jérà.